Ìbẹ̀rẹ̀
Lọ́gán ni gbogbo rẹ̰̀ ṣẹlẹ̀, ní àwọn ọdún kan sẹ́yìn,
Ọmọdékùnrin tí mo jẹ́ di ọkùnrin:
Lójijì ìgbé-ayé mi bẹ̀rẹ̀!
Mo rí ayé níwájú mi— Nítorí náà
Atúlẹ̀ yẹn nítòsí èèkàn àwọn ẹṣin rẹ̀
Nlàágùn lórí ténté òkè àkọ́kọ́,
Lẹ́yìn tí ó ti kúrò níbi olómi náà
Ó la aporo ní àfonífojì ìsàlẹ̀,
Ó sì nrí ẹsẹ̀ òkè láti tú,
Aṣálẹ̀ orí àpáta láti lo irin iṣẹ́ rẹ̀ ní àlòyọ́,
Ààrá nrọ̀ dẹ̀dẹ̀ nínú afẹ́fẹ́,
Ṣónṣó orí òkè dúdú náà sì wà lókè rẹ̀, ó ṣí sílẹ̀
Ó wá ndúró wàyí.
—Jẹ́ kí ó tú ílẹ̀ náà tí ó bá tó bẹ́ẹ̀!